Sáàmù 94 BMY

Ọlọ́run Olùgbẹ̀san Àwọn Olódodo

1 Olúwa Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san,Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san.

2 Gbé ara Rẹ sókè, ìwọ onídàájọ́ ayé;san ẹ̀san fún agbéragaohun tí ó yẹ wọ́n.

3 Báwo ní yóò ti pẹ́ tó, Olúwatí àwọn ẹni búburúyóò kọ orin ayọ̀?

4 Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìgbérága jáde;gbogbo àwọn olùṣebúburúkún fún ìṣògo.

5 Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn Rẹ túútúú, Olúwa:wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní Rẹ̀ lójú.

6 Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò,wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba,

7 Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i;Ọlọ́run Jákọ́bù kò sì kíyèsí i.”

8 Kíyèsí i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyànẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?

9 Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bi?Ẹni tí ó dá ojú?Ó ha lè ṣe láìríran bi?

10 Ẹni tí ń bá orílẹ̀ èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni sọ́nà bí?Ẹni ti ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?

11 Olúwa mọ èrò inú ènìyàn;ó mọ̀ pé aṣán ni wọ́n.

12 Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tíìwọ báwí, Olúwa,ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin Rẹ;

13 Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi,títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.

14 Nítorí Olúwa kò ní kọ̀ àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀;Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní Rẹ̀ sílẹ̀.

15 Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo,àti gbogbo àwọn ọlọ́kàndídúró ṣinṣin yóò tẹ̀ lé e lẹ́yìn.

16 Ta ni yóò dìde fún misí àwọn olùṣe búburú?Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?

17 Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́,èmi fẹ́rẹ̀ má a gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́

18 Nígbà tí mo sọ pé “ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”, Olúwa, ìfẹ́ Rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.

19 Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi,ìtùnú Rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.

20 Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Rẹẹni tí ń fí òfin dìmọ̀ ìwà ìkà?

21 Wọ́n kó ara wọn jọ si olódodowọ́n sì ń dá àwọn aláìsẹ̀ lẹ́bi sí ikú.

22 Ṣùgbọ́n, Olúwa ti di odi alágbára mi,àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹnití mo ti ń gba ààbò.

23 Òun yóò san ẹ̀san ibi wọn fún wọnyóò sì pa wọ́n run nítorí búburú wọn Olúwa Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.