Sáàmù 40 BMY

Ìdúpẹ́ Fún Ìtúsílẹ̀ Àti Àdúrà Fún Ìrànlọ́wọ́

1 Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa;ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.

2 Ó fà mí yọ gòkèláti inú ihò ìparun,láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀,ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta,ó sì jẹ́ kí ìgbesẹ̀ mi wà láìfòyà.

3 Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu,àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa.Ọ̀pọ̀ yóò ríi wọn yóò sì bẹ̀rù,wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa.

4 Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n ọn-nìtí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọntí wọn kò sì yípadà sí agbéraga,tàbí àwọn tí ó yapalọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.

5 Olúwa Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ni àwọn isẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹtí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,wọn ju ohun tíènìyàn leè kà lọ.

6 Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,ìwọ ti sí mi ní etí.Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ni ìwọ kò bèèrè.

7 Nígbà náà ni mo wí pé,“Èmi nìyí;nínú ìwé kíkà nìa kọ ọ nípa temí wí pé.

8 Mo ní inú dídùnláti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ,ìwọ Ọlọ́run mi;Òfin Rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

9 Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlàláàrin àwùjọ ńlá;wòó,èmi kò pa ètè mí mọ́,gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀,ìwọ Olúwa.

10 Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlàsin ní àyà mi,èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́àti ìgbàlà Rẹ̀:èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀àti òtítọ́ Rẹ̀ mọ́kúrò láàrin àwọn ìjọ ńlá.

11 Ìwọ má ṣe,fa àánú Rẹ̀ tí ó rọnúsẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; Olúwajẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ Rẹàti òtítọ́ Rẹkí ó máa pa mí mọ́títí ayérayé.

12 Nítorí pé àìníye ibini ó yí mi káàkiri,ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi,títí tí èmi kò fi ríran mọ́;wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,àti wí pé àyà mí ti kùnà.

13 Jẹ́ kí ó wù ọ́,ìwọ Olúwa,láti gbà mí là; Olúwa,yára láti ràn mí lọ́wọ́.

14 Gbogbo àwọn wọ̀nnìni kí ojú kí ó tìkí wọn kí ó sì dààmúàwọn tí ń wá ọkàn miláti parun:jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìnki á sì dójú tì wọ́n,àwọn tí n wá ìpalára mi.

15 Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Áà! Áá!”ó di ẹni àfọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtijú wọn.

16 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọkí ó máa yọ̀kí inú wọn sì máa dùn sí ọ;kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà Rẹkí o máa wí nígbà gbogbo pé,“Gbígbéga ni Olúwa!”

17 Bí ó ṣe ti èmi ni,talákà àti aláìní ni èmi,ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi.Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ miàti ìgbàlà mi;Má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́,ìwọ Ọlọ́run mi.