Sáàmù 56 BMY

Gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Nígbà Ìdààmú

1 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, nítorí àwọn ènìyàn ń fi ìgbọ́nára lépa mi;ní gbogbo ọjọ́ ni wọn ń kọjú ìjàsí mi, wọn ń ni mi lára.

2 Àwọn ọ̀ta mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn.

3 Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bàmí,èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.

4 Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ Rẹnínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà míkí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?

5 Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi.

6 Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n baWọn ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ miwọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.

7 Wọ́n ha le mú un jẹ gbé?Ní ìbínú Rẹ, Ọlọ́run, wó àwọn ènìyàn yìí lulẹ̀ Ọlọ́run!

8 Kọ ẹkún mi sílẹ̀;kó omije mi sí ìgò Rẹwọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ Rẹ bí?

9 Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndànígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́nípa èyí ní mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi

10 Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ Rẹ̀nínú Olúwa, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ Rẹ̀:

11 Nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi:ẹ̀rù kì yóò bà míkí ni ènìyàn le ṣe sí mi?

12 Mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ lábẹ́ Rẹ Ọlọ́run:èmi o mú ìyìn mi wá fún ọ.

13 Nítorí ìwọ tí gbà mí lọ́wọ́ ikúàti ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú,kí èmí lè máa rìn níwájú Ọlọ́runní ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè.