Sáàmù 144 BMY

Gbàdúrà Fún Ìgbàlà Orílẹ̀ Èdè Àti Ààbò

1 Ìyìn sí Olúwa àpáta mi,ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun,àti ìka mi fún ìjà.

2 Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi,ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi,ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé,ẹni tí ó tẹ́rí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi

3 Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún-ún,tàbi ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa Rẹ̀?

4 Ènìyàn rí bí èmi;ọjọ́ Rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.

5 Tẹ ọ̀run Rẹ ba, Olúwa, kí o sì sọ̀kalẹ̀;tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí, rú èéfín.

6 Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀ta ká;ta ọfà Rẹ kí ó sì dà wọ́n rú.

7 Na ọwọ́ Rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga;gbà mí kí ó sì yọ mí nínú ewukúrò nínú omi ńlá:kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì.

8 Ẹnu ẹni tí ó kún fún èkéẹni tí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ.

9 Èmi yóò kọ orin túntún sí ọỌlọ́run; lára ohun èlò orinolókùn mẹ́wàá èmi yóòkọ orin sí ọ

10 Sí ẹni tí ó fún àwọn ọba ní ìsẹ́gun,ẹni tí ó gba Dáfídì ìránṣẹ́ Rẹ̀lọ́wọ́ pípanirun.

11 Gbàmí kí ó sì yọ mí nínú ewukúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjìtí ẹnu wọn kún fún èké,tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.

12 Kí àwọn ọmọkùnrin wa kí ó dàbí igigbígbin tí ó dàgbà ni ìgba èwe wọn,àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilétí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.

13 Àká wa yóò kúnpẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹàgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún,ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:

14 Àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwokí ó má sí ìkọlù,kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn,kí ó má síi igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.

15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náàtí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀, Ayọ̀ ni fún àwọntí ẹni ti Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.