1 Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,iwọ Ọlọ́run òdodo mi,Fún mi ní ìdánídè nínú ìpọ́njú mi;ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
2 Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹyin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú?Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó,tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ́ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá Ọlọ́run èké?
3 Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo ṣọ́tọ̀ fún ara Rẹ̀; Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.
4 Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀;Nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín,ẹ bà ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.
5 Ẹ rú ẹbọ òdodokí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa.
6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wá?” Olúwa, Jẹ́ kí ojú Rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,
7 Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn miju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.
8 Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà,nítorí ìwọ nìkan, Olúwa, ni omú mi gbé láìléwu.