1 Pa mí mọ́, Ọlọ́run,nítorí nínú Rẹ ni ààbò mí wà.
2 Mo sọ fún Olúwa, “ìwọ ni Ọlọ́run mi,lẹ́yìn Rẹ èmi kò ní ire kan.”
3 Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé,àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.
4 Ìṣòro àwọn wọ̀n ọn nì yóò pọ̀ síiàwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.
5 Olúwa, ni ìní mi tí mo yàn àti ago mi,ó ti pa ohun tí íṣe tèmi mọ́.
6 Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.
7 Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbàmí ní ìyànjú;ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.
8 Mo ti gbé Ọlọ́run ṣíwájú mi ní ìgbà gbogbo.Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi,a kì yóò mì mí.
9 Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,
10 nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú iṣà òkú,tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ Rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.
11 Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní ìwájú Rẹ,pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ.