Sáàmù 105 BMY

Ododo Ọlọ́run Si Ísírẹ́lì

1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orukọ Rẹ̀:Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrin àwọn orílẹ̀ èdè;

2 Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;sọ ti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ gbogbo.

3 Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ Rẹ̀:Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.

4 Wá Olúwa àti ipá Rẹ̀;wa ojú Rẹ̀ nígbà gbogbo.

5 Rantí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,ìyanu Rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,

6 Ẹ̀yin ìran Ábúráhámù ìránṣẹ́ Rẹ̀,ẹ̀yin ọmọkùnrin Jákọ́bù, àyànfẹ́ Rẹ̀.

7 Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa:ìdájọ́ Rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.

8 Ó rántí májẹ̀mú Rẹ̀ láéláé,ọ̀rọ̀ tí ó páláṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran;

9 Májẹ̀mu tí ó ṣe pẹ̀lú Ábúráhámù,àti ìbúra tí ó búra fún Ísáákì.

10 Ó fi da Jákọ́bù lójú gẹ́gẹ́ bí àṣẹsí Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé

11 “Fún ìwọ ní èmi ó fún ní ilẹ̀ Kénánìgẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún”.

12 Nígbà tí wọn kéré níye,wọn kéré jọjọ, àti àwọn àjòjì níbẹ̀

13 Wọn ń lọ láti orílẹ̀ èdè sí orílẹ̀ èdè,láti ìjọba kan sí òmìrán.

14 Kò gba ẹnikẹ́ni láàyè láti pọ́n wọn lójú;ó fi ọba bú nítorí tí wọn:

15 “Má ṣe fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi,má sì ṣe wòlíì mi nibi.”

16 Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náàó sì pa gbogbo ìpèṣè oúnjẹ wọn run;

17 Ó sì rán ọkùnrin kan ṣíwájú wọnJósẹ́fù tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.

18 Wọn fi sẹkẹ́sẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ Rẹ̀a gbé ọrùn Rẹ̀ sínú irin

19 Títí ọ̀rọ̀ tí ó sọ tẹ́lẹ̀ fi ṣẹtítí ọ̀rọ̀ Olúwa fi dá a láre.

20 Ọba ránsẹ́ lọ tú u sílẹ̀àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀

21 Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ Rẹ̀aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,

22 Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ̀, kí ó máaṣe àkóso àwọn ọmọ aládékí ó sì kọ́ àwọn àgbà Rẹ̀ ní ọgbọ́n.

23 Ísírẹ́lì wá sí Éjíbítì;Jákọ́bù sì ṣe àtìpó ní ilé Ámù.

24 Olúwa, sì mú àwọn ọmọ Rẹ̀ bí síió sì mú wọn lágbára jùàwọn ọ̀tá wọn lọ

25 Ó yí wọn lọkàn padà láti korìíra àwọn ènìyànláti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀.

26 Ó rán Mósè ìránṣẹ́ Rẹ̀àti Árónì tí ó ti yàn

27 Wọn ń ṣé iṣẹ́ ìyanu láàrin wọnó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Ámù

28 Ó rán òkùnkùn o sì mú ilẹ̀ ṣúwọn kò sì sọ̀rọ̀ òdì sí ọ̀rọ̀ Rẹ̀?

29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,ó pa ẹja wọn.

30 Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá,èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.

31 Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣnṣin sì dìde,ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn

32 Ó sọ òjò di yìnyín,àti ọ̀wọ́ iná ní ilẹ̀ wọn;

33 Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọnó sì dá igi orílẹ̀ èdè wọn.

34 Ó sọ̀rọ̀, eésú sì dé,àti kòkòrò ní àìníye,

35 Wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn,wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run

36 Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn,ààyò gbogbo ipá wọ́n.

37 Ó mú Ísírẹ́lì jádeti òun ti fàdákà àti wúrà,nínú ẹ̀yà Rẹ̀ kò sí aláìlera kan.

38 Inú Éjíbítì dùn nígbà tí wọn ń lọ,nítorí ẹ̀rù àwọn Ísírẹ́lí ń bá wọ́n.

39 Ó ta awọsánmọ̀ fún ìbòrí,àti iná láti fún wọn ni ìmọ́lẹ̀ lálẹ́

40 Wọn bèèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá,ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọ́n lọ́rùn.

41 Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde;gẹ́gẹ́ bí odò tí ń ṣàn níbi gbígbẹ.

42 Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ Rẹ̀àti Ábúráhámù ìránṣẹ́ Rẹ̀.

43 Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn Rẹ̀ jádepẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ Rẹ̀

44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà,wọn sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà,

45 Kí wọn kí ó le máa pa àṣẹ Rẹ̀ mọ́kí wọn kí ó le kíyèsí òfin Rẹ̀.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.