3 Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́?Ẹni tí tí ń ṣe ohun tí ó tọ́
4 Rántí mi, Olúwa,Nígbà tí ó bá fi ojú rere Rẹ̀ hàn,wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,
5 Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yànkí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyànìní Rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.
6 Àwa ti dẹ́sẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣeàwa ti ṣe ohun tí kò dá aa sì ti hùwà búburú
7 Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Éjíbítìiṣẹ́ ìyanu Rẹ kò yé wọnwọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú Rẹgẹ́gẹ́ bí wọn ṣe sọ̀tẹ̀ sí ọ níbi òkun, àní nibi òkun pupa
8 Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ Rẹláti jẹ́ kí agbára ńlá Rẹ di mímọ̀
9 O bá òkun pupa wí, ó sì gbẹ;o sì mú wọn la ìbú já bí ihà