1 Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fúnMá ṣe dákẹ́
2 Nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tànti ya ẹnu wọn sí miwọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi
3 Wọn fi ọ̀rọ̀ ìrira yí mi káàkiri;wọ́n bá mi ja láìnídìí
4 Nípo ifẹ̀ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi,ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà.
5 Wọ́n sì fi ibi san ire fún miàti ìríra fún ìfẹ́ mi.