14 Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba Rẹ̀ kíó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ OlúwaMá ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò
15 Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwakí o le ge ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
16 Nítorí kò rántí láti ṣàánú,ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíní sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú,kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn.
17 Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí Rẹ̀:bi inú Rẹ̀ kò ti dùn si ire, bẹ́ẹ̀ ni ki ó jìnnà sí ì.
18 Bí ó ti fi ègún wọ ará Rẹ̀ lásọ bí ẹ̀wùbẹ́ẹ̀ ni kí ó wá si inú Rẹ̀ bí omi
19 Jẹ́ kí o rí fún un bí aṣọ tí a dàbòó níara, àti fún àmùrè ti ó fi gbàjá nígbà gbogbo
20 Èyí ni èrè àwọn ọ̀ta mi làti ọwọ́ Olúwa wá;àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀kàn mi.