28 Wọ́n o máa gégùn-ún, ṣùgbọ́n ìwọ má súré;Nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n,ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ Rẹ yóò yọ̀
29 Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjúkí á sì fi ìdàrú dàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù.
30 Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yìn Olúwa gidigidiní àárin ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín
31 Nítorí ó dúró ni apá ọ̀tún aláìníláti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ń dá ọkàn Rẹ̀ lẹ́bi.