1 Olúwa sọ fún Olúwa mi, pé ìwọ jòkòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá Rẹ̀ di àpótí ìtisẹ̀ Rẹ
2 Olúwa yóò na ọ̀pá agbára Rẹ̀láti Síónì wá, ìwọ jọba láàrin àwọn ọ̀tá Rẹ.
3 Àwọn ènìyàn Rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwání ọjọ́ ìjáde ogun Rẹ, nínú ẹwà mímọ́,láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà Rẹ.
4 Olúwa ti búra, kò sí ní yí ọkàn padà pé,ìwọ ní àlúfà títí láé, titẹ̀ àpẹẹrẹ Melekisédékì.
5 Olúwa ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ niyóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú Rẹ̀
6 Yóò ṣe ìdájọ́ láàrin kènfèrí,yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara;yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.