1 Ẹ máa yin Olúwa, yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,ẹ yin orúkọ Olúwa.
2 Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa látiìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
3 Láti ìlà òòrun títí dé ìwọ Rẹ̀orúkọ Olúwa ni kí á máa yìn.
4 Olúwa ga lórí gbogbo ayé,àti ògo Rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.
5 Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa,tí ó gbé ní ibi gíga.
6 Tí ó Rẹ ara Rẹ̀ sílẹ̀ láti wòòun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!
7 Ó gbé òtòsì dìde láti inú erùpẹ̀, àti péó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.