116 Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ,kí èmi kí ó lè yèMá sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.
117 Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu;nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin Rẹ.
118 Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó sìnà kúrò nínú òfin Rẹ,nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.
119 Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọyọ kúrò bí i ìdàrọ́;nítorí náà, èmi fẹ́ òfin ẹ̀.
120 Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí Rẹ̀:èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin Rẹ
121 Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́:má ṣe fi mi sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.
122 Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ Rẹ dájú:má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.