1 Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà Rẹ̀
2 Nítorí tí ìwọ yóò jẹ isẹ́ ọwọ́ Rẹìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ
3 Obìnrin Rẹ yóò dà bí àjàrà rereeléso púpọ̀ ní àárin ilé Rẹ;àwọn ọmọ Rẹ yóò dà bí igi olífì tí ó yí tábìlì Rẹ ká.
4 Kíyèsíi pé, bẹ́ẹ̀ ni a o bù síi fún ọkùnrin náà,tí o bẹ̀rù Olúwa.
5 Kí Olúwa kí o bù síi fún ọ láti Síónì wá,kí ìwọ kí ó sì máa rí ireJérúsálẹ́mù ní ọjọ́ ayé Rẹ gbogbo.
6 Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí o sì máa rí àti ọmọ dé ọmọ Rẹ;àti àlàáfíà lára Ísírẹ́lì.