4 Nítorí ti kò si ọ̀rọ kan ní ahọ́n mi,kíyèsíi, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátapáta.
5 Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,ìwọ sì fi ọwọ́ Rẹ lé mi.
6 Irú ìmọ̀ yìí ṣe ohun ìyanu fún mi jù;ó ga, èmi kò le mọ̀.
7 Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ní ọwọ́ ẹ̀mí Rẹ?Tàbí níbo ní èmi yóò sáré kúrò níwájú Rẹ?
8 Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀;bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú,kíyèsí i, ìwọ wà níbẹ̀.
9 Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀,kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin òkun;
10 Àní níbẹ̀ náà ni ọwọ́ Rẹ̀ yóò fà míọwọ́ ọ̀tún Rẹ yóò sì dì mí mú.