6 Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi; Olúwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7 Ọlọ́run Olúwa, agbára ìgbàlà mí,ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.
8 Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún ún;Má ṣe kún ọgbọ́n búburú Rẹ̀ lọ́wọ́;kí wọn kí ó máa baà gbé ara wọn ga. Sela
9 Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi kákiri ni,jẹ́ kí ìka ètè ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.
10 A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára:Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná,sínú ọ̀gbun omi jínjìn,kí wọn kí ó má bà le dìde mọ́.
11 Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹṣẹ̀ múlẹ̀ ní ayé;ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.
12 Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró,yóò si ṣe ètò fun àwọn tálákà