1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa,fi ìyìn fún Olúwa, ìwọ ọkàn mi
2 Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mièmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run,níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè.
3 Ẹ má ṣe ní ìgbẹkẹ̀lé nínú àwọn ọmọ aládé,àní, ọmọ ènìyàn,lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.
4 Ẹ̀mí Rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀ Rẹ̀:Ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo:
5 Ìbùkún ni fún ẹni tíỌlọ́run Jákọ́bù ń ṣe ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀tí ìrètí Rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run Rẹ̀,
6 Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayéòkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn Olúwa, tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí láéláé
7 Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni láratí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa Olúwa, tú àwọn oǹdè sílẹ̀ (ẹlẹ́wọ̀n)