2 Ó mú mi dùbúlẹ̀ síbi pápá oko tútùÓ mú mi lọ síbi omí dídákẹ́ rọ́rọ́;
3 Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípòÓ mú mi lọ sí ọ̀nà ododonítorí orúkọ Rẹ̀.
4 Bí mo tílẹ̀ ń rìnLáàrin àfonífojì òjiji ikú,èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;nítorí ìwọ wà pẹ̀lú ù mi;ọ̀gọ Rẹ àti ọ̀pá à Rẹwọ́n ń tù mi nínú.
5 Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú ù miní ojú àwọn ọ̀tá à mi;ìwọ ta òróró sí mi ní orí;ago mí sì kún àkún wọ́ sílẹ̀.
6 Nítòótọ, ire àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìnní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwatítí láéláé.