2 Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ;Má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì míMá ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀ta mi ó yọ̀ mí.
3 Ẹni tí ó dúró tì ọ́;ojú kí yóò tìíàwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìíni kí ojú kí ó tì.
4 Fi ọ̀nà Rẹ hàn mí, Olúwa,kọ mi ní ipa tìrẹ;
5 ṣe amọ̀nà mi nínú ọ̀títọ́ ọ Rẹ, kí ò si kọ́ mi,Nítoríi ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi;ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.
6 Rántí, áà! Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ̀ ńlá,torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́
7 Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mitàbí ìrékọjáà mi;gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ Rẹ̀ rántíì minítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa.
8 Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa:nítorí náà ó kọ́ àwọn ẹlẹ́sẹ̀ ni ọ̀nà náà.