22 Ìwọ́ ti ríiÌwọ Olúwa:Má ṣe dákẹ́!Ìwọ Olúwa,Má ṣe jìnnà sí mi!
23 Jí dìde!Ru ara Rẹ̀ sókè fún ààbò mi,fún ìdí mi,Ọlọ́run mi àti Olúwa mi!
24 Dá mi láre,ìwọ Olúwa,Ọlọ́run mi,gẹ́gẹ́ bí òdodo Rẹ,kí o má sì ṣe jẹ́ kíwọn kí ó yọ̀ lórí mi!
25 Má ṣe jẹ́ kí wọn wínínú ara wọn pé,“Áà! Àti rí ohun tí ọkànwa ń fẹ́:Má ṣe jẹ kí wọn kí ó wí pé,a ti gbé e mì.”
26 Kí ojú kí ó tì wọ́n,lí wọn kí ó sì dààmú pọ̀,tí ń yọ̀ sí ìyọnu mikí a fi ìtìjú àti àbùkù wọ̀ wọ́n ní aṣọtí ń gbéraga sí mi.
27 Jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ìdáláre mifó fún ayọ̀ àti ìdùnnú,kí wọn máa sọ ọ́ titi lọ,pé gbígbéga ni “Olúwasí àlàáfíà ìránṣẹ Rẹ̀”.
28 Nígbà náà ni ahọ́n mi yóò máasọ̀rọ̀ òdodo Rẹ,àti ìyìn Rẹ ní gbogbo ọjọ́.