1 Ìrékọjá sọ̀rọ̀ sí ènìyàn búburújinlẹ̀ nínú ọkàn wọn;Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò síníwájú ojú wọn
2 Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọntítí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra.
3 Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òun ẹ̀tàn;wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀;
4 Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkànígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn:wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára:wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.