5 Olúwa Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ni àwọn isẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹtí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,wọn ju ohun tíènìyàn leè kà lọ.
6 Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,ìwọ ti sí mi ní etí.Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ni ìwọ kò bèèrè.
7 Nígbà náà ni mo wí pé,“Èmi nìyí;nínú ìwé kíkà nìa kọ ọ nípa temí wí pé.
8 Mo ní inú dídùnláti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ,ìwọ Ọlọ́run mi;Òfin Rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”
9 Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlàláàrin àwùjọ ńlá;wòó,èmi kò pa ètè mí mọ́,gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀,ìwọ Olúwa.
10 Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlàsin ní àyà mi,èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́àti ìgbàlà Rẹ̀:èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀àti òtítọ́ Rẹ̀ mọ́kúrò láàrin àwọn ìjọ ńlá.
11 Ìwọ má ṣe,fa àánú Rẹ̀ tí ó rọnúsẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; Olúwajẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ Rẹàti òtítọ́ Rẹkí ó máa pa mí mọ́títí ayérayé.