1 Dámiláre, Ọlọ́run mi,kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè aláìwà-bí-Ọlọ́run:yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.
2 Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi.Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀?Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́,nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?
3 Ran ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ Rẹ jáde,jẹ́ kí wọn ó máa dààbò bò mí;jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ Rẹ,sí ibi tí ìwọ ń gbé.
4 Nígbà náà ní èmi o lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,sí Ọlọ́run ayọ̀ mí àti ìdùnnú mi,èmi yóò yin ọ pẹ̀lú dùùrù,ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.
5 Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí?Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi?Fi ìrètí Rẹ sínú Ọlọ́run,nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun niOlùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.