6 Wọn ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi:a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjúwọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi:ṣùgbọ́n wọn ti jìn ṣíbẹ̀ fún ara wọn.
7 Ọkàn mi tí múra Ọlọ́run;ọkàn mí ti múra, èmi ó kọrin èmi ó si máa kọrin ìyìn.
8 Jí, ìwọ ọkàn mi!Jí, ohun orin èlò àti dùùrù!Èmi tìkárami, yóò si jí ní kùtùkùtù.
9 Èmi ó máa yín ọ, Olúwa, láàrin àwọn orílẹ̀ èdè;èmi ó máa kọrin sí ọ láàrin àwọn ènìyàn.
10 Nítorí títóbi ní ìfẹ́ Rẹ, tí ó dé ọ̀run;òtítọ́ Rẹ tàn dé àwọ̀sánmọ̀.
11 Gbígbéga ni ọ, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ;kí ògo Rẹ̀ kí ó ju gbogbo ayé lọ.