3 Ní inú ìyá wọn wá, ni eniyàn búburú tí sìnà lojukan náà tí a ti bí wọnwọn a máa ṣèké.
4 Ọ̀rọ̀ wọn dà bí ọ̀rọ̀ ejò,gẹ́gẹ́ bí ti sèbé tí ó dítí Rẹ̀,wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara Rẹ̀ ni etí
5 Tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atinilójú,bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.
6 Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run;ní ẹnu wọnká ọ̀gan àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa.
7 Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń ṣàn lọ;nígbà tí ó bá fa ọfà Rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.
8 Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí Rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbébí ọmọ ti oṣu Rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí òòrùn.
9 Kí ìkòkò yín kì o tó mọ̀ ìgbóná ẹ̀gún;ìbá tutù, ìbá ma jò, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.