2 Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń ku lọ; Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.
3 Ọkàn mi wà nínú ìrora.Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó?
4 Yípadà, Olúwa, kí ó sì gbà mí;gbà mí là nípa ìfẹ́ Rẹ tí kì í ṣákìí.
5 Ẹnikẹ́ni kò sì rántí Rẹ nígbà tí ó bá kú.Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú iṣà òkú?
6 Agara ìkérora mi da mi tán;gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkúnmo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.
7 Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́;wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.
8 Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.