5 Ẹnikẹ́ni kò sì rántí Rẹ nígbà tí ó bá kú.Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú iṣà òkú?
6 Agara ìkérora mi da mi tán;gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkúnmo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.
7 Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́;wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.
8 Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.
9 Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú; Olúwa ti gba àdúrà mi.
10 Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú;wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.