6 Wọ́n gbìmọ̀ àìsòdodo, wọn wí pé,“A wa ti parí èrò tí a gbà tán”lóòtọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.
7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà;wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.
8 Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́nGbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.
9 Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rùwọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́runwọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.
10 Jẹ́ kí Olódodo kí o yọ̀ nínú Olúwayóò sì rí ààbò nínú Rẹ̀Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ni àyà yóò máa yìn ín.