2 kí ọ̀nà Rẹ̀ le di mímọ̀ ní ayé,ìgbàlà Rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè.
3 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;kí gbogbo ènìyàn kí o yìn ọ!
4 Kí orílẹ̀ èdè kí o yọ̀, kí o sì kọrin fún ayọ̀,nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyànìwọ si jọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.
5 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela
6 Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè Rẹ̀ wá, Ọlọ́run,Ọlọ́run wa yóò bùkún fún wa.
7 Ọlọ́run yóò bùkún fún wa,àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù Rẹ̀.