1 Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là, Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.
2 Kí àwọn tí ń wá ọkàn mikí a dojú tì wọ́n, kí wọn sì dààmú;kí àwọn tó ń wá ìparun miyí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.
3 Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrèìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Áà! Áà!”
4 Ṣùgbọ́n kí àwọn tí o ń wà ọ ó máa yọ̀kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa Rẹ,kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà Rẹ máa wí pé,“Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”
5 Ṣíbẹ̀ mo jẹ́ òtòsì, mo sì jẹ́ aláìní;wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùtúsílẹ̀ mi; Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.