11 Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;lépa Rẹ̀ kí ẹ sì munítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”
12 Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run;wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti rànmí lọ́wọ́.
13 Jẹ́ kí wọn kí ó dààmúkí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mikí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkùbò àwọn tí ń wá ìpalára mi.
14 Ṣùgbọ́n ní tèmí, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi;èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sì i.
15 Ẹnu mí yóò sọ nípa ti òdodo Rẹ,ti ìgbàlà Rẹ ni gbogbo ọjọ́lóòtọ́, èmi kò mọ́ iye Rẹ̀.
16 Èmi ó wá láti wá kéde agbára Olúwa Ọlọ́run;èmi ó kéde òdodo Rẹ̀ nìkan.
17 Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ tí kọ́ mítítí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀.