16 Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí,O jẹ́ ìnilára fún mi.
17 Tí tí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run;Nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi,
18 Lótítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.
19 Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìíbí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan!Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọn pátapáta!
20 Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí,bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa,ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.
21 Nígbà tí inú mi bàjẹ́àti ọkàn mi sì korò,
22 Mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye;mo jẹ́ ẹranko ní ìwájú Rẹ.