7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdajọ́;Òun Rẹ̀ ẹnìkan sílẹ̀, ó sí ń gbé ẹlòmíràn ga.
8 Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà,ọtí wáìnì náà sì pọ́n,ó kún fún àdàlú, ó fún ọtí àdàlú tí a pòpọ̀ mọ́ òórùn dídùntí ó tú jáde, àti búburú ayé gbogbomú u sílẹ̀ pátapáta.
9 Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn Rẹ títí láé;Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jákọ́bù (Ísírẹ́lì)
10 Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.