1 Ọlọ́run àwọn orílẹ̀ èdè ti wà ilẹ̀ ìní Rẹ;wọn ti bá tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ jẹ́,wọn di Jérúsálẹ́mù kù sí òkìtì àlàpà.
2 Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ,ẹran ara àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀.
3 Wọ́n tú ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omiyí Jérúsálẹ́mù ká,kò sì sí àwọn tí yóò sìn wọ́n.
4 Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí o yí wa ká,àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wá ká.
5 Nígbà wo, Olúwa? Ní ìwọ o máa bínú títí láé?Yóò ti pẹ́ tó ti òwú Rẹ̀ yóò ha jò bi iná?
6 Tú ìbínú Rẹ̀ jáde sí orílẹ̀-èdètí kò ní ìmọ̀ Rẹ,lórí àwọn ìjọbatí kò pe orúkọ Rẹ;
7 Nítorí wọ́n ti run Jákọ́bùwọ́n sì sọ ibùgbé Rẹ̀ di ahoro