3 Wọ́n tú ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omiyí Jérúsálẹ́mù ká,kò sì sí àwọn tí yóò sìn wọ́n.
4 Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí o yí wa ká,àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wá ká.
5 Nígbà wo, Olúwa? Ní ìwọ o máa bínú títí láé?Yóò ti pẹ́ tó ti òwú Rẹ̀ yóò ha jò bi iná?
6 Tú ìbínú Rẹ̀ jáde sí orílẹ̀-èdètí kò ní ìmọ̀ Rẹ,lórí àwọn ìjọbatí kò pe orúkọ Rẹ;
7 Nítorí wọ́n ti run Jákọ́bùwọ́n sì sọ ibùgbé Rẹ̀ di ahoro
8 Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùnjẹ́ kí àánú Rẹ yà kánkán láti bá wa,nítorí ti a Rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi.
9 Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa,fún ògo orukọ Rẹ;gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnítorí orúkọ Rẹ.