6 Tú ìbínú Rẹ̀ jáde sí orílẹ̀-èdètí kò ní ìmọ̀ Rẹ,lórí àwọn ìjọbatí kò pe orúkọ Rẹ;
7 Nítorí wọ́n ti run Jákọ́bùwọ́n sì sọ ibùgbé Rẹ̀ di ahoro
8 Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùnjẹ́ kí àánú Rẹ yà kánkán láti bá wa,nítorí ti a Rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi.
9 Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa,fún ògo orukọ Rẹ;gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnítorí orúkọ Rẹ.
10 Àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì máa wí pé,“Níbo ni Ọlọ́run wọn wà?”ní ojú wa.Kí a mọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdèkí ó sì gbẹ̀san àwọn ẹ̀jẹ̀ ìránṣẹ́ Rẹ̀ tí a tú jáde.
11 Jẹ́ kí ìmí ẹ̀dùn oǹdè náà wá ṣíwájú Rẹ,gẹ́gẹ́ bí títóbi agbára Rẹìwọ ṣe ìtọ́jú àwọn ti a dá lẹ́bí ikú.
12 San án padà sí àyà àwọn aládùúgbò wa nígbà méjenípa ẹ́gàn tí wọn tí gàn ọ́ Olúwa.