2 Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmúni o ti yan ìyìnnítorí àwọn ọ̀ta Rẹ,láti pa àwọn ọ̀ta àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.
3 Nígbà tí mo ro ọ̀run Rẹ,iṣẹ́ ìka Rẹ,òṣùpá àti ìràwọ̀,tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,
4 kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa Rẹ̀,ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú Rẹ̀?
5 Ìwọ ṣeé ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju ẹ̀dá ọ̀run lọìwọ sì dée ní adé ògo àti ọlá.
6 Ìwọ mu-un jọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ;ìwọ si fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ Rẹ̀:
7 gbogbo ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran,àti ẹranko ìgbẹ́,
8 ẹyẹ ojú ọrun,àti ẹja inú òkun,àti ohun tí ń wẹ nínú ipa òkun.