1 Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,ó ṣe ìdájọ́ láàárin àwọn “ọlọ́run òrìṣà”:
2 “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìsòdodokí ó sì ṣe ojú ìṣájú sí àwọn ènìyàn búburú?
3 Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.
4 Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;gbà wọ́n kùró lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.