1 Ibùgbé Rẹ̀ ti lẹ́wà tó, Olúwa Olódùmarè!
2 Ọkàn mí ń fà nítòótọ́ó tilẹ̀ pòùngbẹ fún àgbàlá Olúwaàyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀sí Ọlọ́run alààyè.
3 Nítòotọ́ ologóṣẹ ri ilé,ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara r,níbi tí yóò máa pá ọmọ Rẹ̀ mọ́ sí:ibùgbé ní tòsí pẹpẹ Rẹ, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.
4 Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé Rẹ;wọn o máa yìn ọ́ títí láé.
5 Ìbùkún ní fún àwọn tí agbára wọn wà nínú Rẹàwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.
6 Àwọn tí ń la àfonífojì omije lọwọn sọ ọ́ di kàngaàkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó;
7 Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipátítí tí ọ̀kọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Síónì.