2 Kí a to bí àwọn òkè nlaàti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé,láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.
3 Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀,wí pé “padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn”.
4 Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú Rẹ,bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
5 Ìwọ gbá ènìyàn dánù nínú oorun ikú;wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
6 Lótìítọ́ ní òwúrọ́ ó yọ tuntunní àsálẹ́ ní yóò gbẹ tí yóò sì Rẹ̀ dànù.
7 A pa wá run nípa ìbínú Rẹnípa ìbínú Rẹ ara kò rọ̀ wá.
8 Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú Rẹ,àti ohun ìkọ̀kọ̀ wà nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú Rẹ,