6 Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò,wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba,
7 Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i;Ọlọ́run Jákọ́bù kò sì kíyèsí i.”
8 Kíyèsí i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyànẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?
9 Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bi?Ẹni tí ó dá ojú?Ó ha lè ṣe láìríran bi?
10 Ẹni tí ń bá orílẹ̀ èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni sọ́nà bí?Ẹni ti ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?
11 Olúwa mọ èrò inú ènìyàn;ó mọ̀ pé aṣán ni wọ́n.
12 Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tíìwọ báwí, Olúwa,ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin Rẹ;