1 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí OlúwaẸ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.
2 Ẹ jẹ́ kí a wá sí ìwájú Rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́kí a sì pòkìkí Rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlòorin àti ìyìn.
3 Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.
4 Ní ọwọ́ Rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.