2 Ẹ jẹ́ kí a wá sí ìwájú Rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́kí a sì pòkìkí Rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlòorin àti ìyìn.
3 Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.
4 Ní ọwọ́ Rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.
5 Tirẹ̀ ni òkun, nítorí òun ni ó dá aàti ọwọ́ Rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.
6 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a forí balẹ̀ kí a sìn-ín,Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú Olúwa ẹni tí ó dá wa;
7 Nítorí òun ni Ọlọ́run waàwa sì ni ènìyàn pápá Rẹ̀,àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ Rẹ̀Lónìí ti ìwọ bá gbọ́ ohùn Rẹ̀,
8 Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Méríbà,àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ni Másà ni ihà,