12 Bí ìlà òòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀ òòrunbẹ́ẹ̀ ní ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.
13 Bí bàbá ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ Rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀;
14 Nítorí tí ó mọ dídá wa,ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.
15 Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ Rẹ̀ dà bí koríko,ó gbilẹ̀ bí ìtànnà ewéko ìgbẹ́;
16 Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí Rẹ̀,kò sì rántí ibùjókòó Rẹ̀ mọ́.
17 Ṣùgbọ́n láti ayé rayé ni ìfẹ́ Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀,àti òdodo Rẹ̀ wà láti ọmọ dé ọmọ
18 Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú Rẹ̀ mọ́àti àwọn tí ó rántí òfin Rẹ̀ láti ṣe wọ́n.