1 Ìgbẹ́kẹ̀lé mí wà nínú Olúwa.Báwo ní ẹ̀yin o ṣe sọ fún ọkàn mi pé:“Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè Rẹ.
2 Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà Rẹ̀;wọn ti ọfà wọn sí ojú okùnláti tafà níbi òjìjìsí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin.
3 Nígbà tí ìpìlẹ̀ ba bàjẹ́kí ni olódodo yóò ṣe?”
4 Olúwa ń bẹ nínú tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ̀; Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ Rẹ̀ ní ọ̀run.Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn;ojú Rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.
5 Olúwa ń yẹ olódodo wò,ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ ìwà ipáni ọkàn Rẹ̀ kórìíra.
6 Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jòẹ̀yín iná àti ìmí ọjọ́ tí ń jó;àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.
7 Nítorí olódodo ní Olúwa,o fẹ́ràn òdodo;ẹni ìdúróṣinṣin yóò sì rí i.