4 Olúwa ń bẹ nínú tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ̀; Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ Rẹ̀ ní ọ̀run.Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn;ojú Rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.
5 Olúwa ń yẹ olódodo wò,ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ ìwà ipáni ọkàn Rẹ̀ kórìíra.
6 Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jòẹ̀yín iná àti ìmí ọjọ́ tí ń jó;àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.
7 Nítorí olódodo ní Olúwa,o fẹ́ràn òdodo;ẹni ìdúróṣinṣin yóò sì rí i.