3 Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;nítorí náà àwa ń yọ̀.
4 Olúwa mú ìkólọ wa padà,bí ìṣàn omi ní gúsù.
5 Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìnyóò fi ayọ̀ ka.
6 Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,lóòtọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,yóò sì ru ìtí Rẹ̀.