1 Bí kò ṣè pé Olúwa bá kọ́ ile náààwọn tí n kọ ọ ńṣiṣẹ́ lásán ni;bí kò sé pé Olúwa bá pa ilú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.
2 Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtùlati pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ́ làálàá;bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ire fún olùfẹ́ Rẹ̀ lójú ọ̀run.
3 Kíyèsí i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa:ọmọ inú sì ni èrè Rẹ̀.
4 Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe
5 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ààbò Rẹ̀ kún fún wọn;ojú kì yóò tì wọ́n,ṣùgbọ́n wọn yóò sẹ́gun àwọn ọ̀ta ní ẹnu ọ̀nà.