30 Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà Rẹ̀ pé,a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwaòun ni àpáta ààbòfún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.
31 Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa?Ta ní àpátà bí kò ṣe Olúwa wa?
32 Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrèó sì mú ọ̀nà mi pé.
33 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín;ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.
34 Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíja;apá mi lè tẹ ọrùn idẹ
35 Ìwọ fi àṣà ìṣẹ́gun Rẹ̀ fún mi,ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ gbé mí sókè;àti ìwà ìpẹ̀lẹ́ Rẹ̀ sọ mi di alágbára àti ẹni ńlá.
36 Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ mi di ńlá ní ìṣàlẹ̀ mi,kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.